Wednesday, 01 May 2024

Atupa

Atupa (Weird but true!!.) A narration of weird but through stories in Yoruba Language.

Ǹjẹ́ mímu omi ilá ní àràárọ̀ le ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà?

 
  •  

Ọ̀rọ̀: Jíjí mu omi ilá ní àràárọ̀ ń ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà. 

Ọ̀rọ̀ pé jíjí mú omi ilá ní àràárọ̀ ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ ìṣini lọ́nà nítorí pé wọn ò tíì fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ìlera. 

Alaye lekunrere

Lọ́jọ́ Kínní oṣù kẹ́jọ ọdún 2021, aṣàmúlò ìtàkùn ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ Facebook kan, Aramide Health Tips kọ ọ̀rọ̀ kan pé “jíjí mu omi ilá ní àràárọ̀ kùtùkùtù ń ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà”. 

Nínú ohun tó kọ, ó ṣe àfihàn pé ilá ní àwọn èròjà tó ń ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà. Omi ilá máa ń ṣe ìrànwọ́ mimu àdínkù bá èròjà to máa ń kórajọpọ̀ di agbára (ṣúgà) inú ẹ̀jẹ̀. 

Ẹ̀wẹ̀, àwọn mìíràn ti dábàá pé mímú omi ilá máa ń mú àdínkù bá ìfarahàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà. Wọ́n máa ń pèsè ohun mímu náà nípa rírẹ apó ilá sínú omi mọ́jú ọjọ́ kejì. Lára àwọn èròjà asaralóore inú ilá yóò sì tọ̀ro sínú omi náà. 

      Àfihàn ohun tó kọ sí orí ìtàkùn ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ Facebook

 

ÌFÌDÍMÚLẸ̀

Kí ni ilá?

Ilá jẹ́ èso orí igi ohun ọ̀gbìn olódòdó kan. Wọ́n máa ń gbin ilá ni agbègbè tí ojú ọjọ́ rẹ̀ ọ̀ gbóná jù, ní bí àwọ̀ ewé rẹ ṣe máa ń wuni jọjọ.

Ilá tún jẹ́ ohun tó máa ń pèsè èròjà asaralóore, amáradán àti amárale. Ó ní omi tó ń tọ́, tó àwọn èèyàn sì máa ń lò láti mú ọbẹ̀ ki. Ó jé ohun ọ̀gbìn tó ṣe kókó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè nítorí àǹfààní ara rẹ̀. Bákannáà, àwọn ènìyàn lè ṣe àmúlò onírúurú ẹ̀yà ara ohun ọ̀gbìn náà, bíi ewé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ tàbí èyí tó ti dàgbà, òdòdó, ilá fúnra rẹ̀, èso inú ilá àti igi rẹ̀.

Àwọn èròjà Asaralóore inú ilá

Àkọsílẹ̀ ní Àjọ elétò ọ̀gbìn ikẹ Amerika (USDA)  sọ pé agolo ilá kan tó jẹ́ nkan bí ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n ní àwọn èròjà wọ̀nyí :

Èròjà àṣà fihàn agbára – ìwọ̀n mẹ́tàlélọ́gbọ̀n 

Èròjà afúnnilẹ́jẹ̀ – ìwọ̀n kan àti ẹ̀sún mẹ́sàn-an

Ọ̀rá – ìwọn òdo ó lè ẹ̀sún méjì

Èròjà afúnnilàgbára – ìwọ̀n méje ó lé ẹ̀sún márùn-ún 

Èròjà amóhúnjesinlẹ̀ – ìwọ̀n mẹ́ta ó lé esun meji

Èròjà akórajọpọ̀ di agbára – ìwọ̀n kan ó lé ẹ̀sún márùn-ún

Èròjà amárale – ìwọ̀n àádọ́rùn ó lè seun márùn-ún 

Àwọn èròjà asaralóore yòókù – ìwọ̀n ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta lè mẹrin. 

Ilá jẹ́ èso tí wọ́n pọ́nlé torí ọ̀pọ̀ èròjà tó sodo sí inú rẹ̀.,bíi amárale, amárajọ̀lọ̀, amégungun le, afuúnnilọ́ràá, àti àwọn èròjà mìíràn. 

Ẹ̀wẹ̀, àrídájú pé ilá ní àwọn èròjà tó ń dènà ìtọ̀ ṣúgà ń pọ̀ síi Wàyí, ní bí ọ̀pọ̀ àyẹ̀wò ṣe ń fìdí ilá múlẹ̀ pé ó ń mú adinku bá èròjà to ń kórajọọpọ̀ di agbára.

Irú rẹ̀ sì ni ohun tí Aramide Health Tips kọ sí ìtàkùn ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ Facebook, pé jíjí mú omi ilá ní àárọ̀ kutu máa ń ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.

Àfihàn ẹ̀ẹ̀keji ohun tó kọ sí orí ìtàkùn ìbáraenidọ́rẹ̀ẹẹ́ Facebook

 

Kí ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà?

Gẹ́gẹ́ bí àjọ elétò ìlera àgbáyé (WHO) ṣe kọọ́ sílẹ̀, ìtọ̀ ṣúgà jẹ́ àìsàn alágbára tó máa ń wáyé nígbà tí ẹ̀yà ara tó máa ń yí ṣúgà padà di agbára nínú ẹ̀jẹ̀ ò bá lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Onírúurú àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ẹ̀yà Kínní, àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ẹ̀yà kéjì, àìsàn ìtọ̀ ṣúgà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà, èyí tí nǹkan kan pàtó ń ṣe okùnfà, àti èyí tó nííse pẹ̀lú ilé ìtọ̀. Tẹ́lẹ̀ ná, níní èròjà tó jọ mọ́ ṣúgà jẹ́ ewu fún àgọ̀ ara. Ó lè ba ojú, kíndìnrín àti ẹ̀yà ara tó ń bá ọpọlọ ṣiṣẹ́ jẹ́. Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà tún leè ṣe okùnfà àìsàn ọkàn, rọpárọsẹ̀ àti ní nílò láti gé apá àbí ẹsẹ̀ irú ẹni tí àìsàn náà ń bá fíra.

Ó ṣe kókó láti fi sí ọkàn pe onírúurú iṣẹ́ ìwádìí ni wọ́n ti ṣe lórí ipa ilá nínú ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ṣùgbọ́n lórí ẹranko nìkan, tí wọ́n ò sì tíì rí ibi fi ọ̀rọ̀ náà tì sí lórí ipa rẹ̀ lára ènìyàn.

Onímọ̀ nípa oúnjẹ asaralóore kan, Tolu Arowolo sọ pé kò jẹ́ titun pé ilá ní èròjà asaralóore gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀gbìn, ṣùgbọ́n wọn ò tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ó ní èròjà tó ń sọ ṣúgà di agbára nínú ènìyàn.

Ó sọ pé “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti gbọ́ nípa pé jíjí mú omi ilá ní àràárọ̀ kùtùkùtù ń ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ohun tí àwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ asaralóore ni pé ó jẹ́ ohun ọ̀gbìn tó dára nítorí èròjà onírúurú tó sodo sínú rẹ̀.” 

Onímọ̀ eto ìlera kan, Dókítà Ademola Ayodele sọ pé ọ̀rọ̀ lórí pé wọ́n leè ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà nípa mímu omi ilá, dàbí pé kò ṣeé ṣe.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ,” Nínú ìmọ̀ ìlera, kìí se pé wọ́n leè ṣe iyèméjì lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n Wọ́n tún leè jiyàn rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, a ní láti mọ ohun tí ó ń ṣe okunfa àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ó jẹ́ àì ní èròjà tó ń sọ ṣúgà di agbára. Wàyí, ilá ò ní mú àdínkù bá èròjà to ń sọ ṣúgà di agbára, báwo ni yóò ṣe wá ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà?”

Ó ṣeé ṣe tí a bá wòó síwájú síi, ó lè ní àǹfààní nípa ṣíṣe àmójútó ewu rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwòsàn pato wàyí jẹ́ yálà ìpèsè èròjà tó ń sọ ṣúgà di agbára, àbí níní oògùn tí yóò mú kí èròjà ọ̀un tó ti wà ní àgọ́ ara túbọ̀ gba agbára síi. Fún ìdí èyí, kò sí onímọ̀ eto ìlera tó leè gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́.”

Onímọ̀ eto ìlera ààtọ̀ lọ kan ni ile iwosan ìkọ́ṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ Fásítì ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ìlú Ondo (UNIMEDTH), Dókítà Adenike Ẹnikuomeyin sọ pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ lórí pé mímu omi ilá leè ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà nítorí pé wọn ò tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ìmọ̀ ètò ìlera.

Ó sọ pé, “Rárá, tí ó  bá jẹ ilá, ó dára fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀gbìn afara pẹ́ ewébẹ̀, ṣùgbọ́n kò ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ìdí sì ni èyí tí a fi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àìsàn ìtọ̀ ṣúgà tó ti fẹ́ yíwọ́ tí wọ́n ń gbé wá fún wa ní ilé ìwòsàn.”

Bẹ́ẹ̀, kò sí ohun tó jọọ́, wọn ò tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin, kò sì sí ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. N óò gba àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣeé, kí wọ́n lè yẹra fún gbígbé àìsàn ojú, kíndìnrín àti ọkàn lọ sí ilé ìwòsàn, tó fi mọ́ àwọn àìsàn mìíràn. Irọ́ ni pé mímu omi ilá ń ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà.

Àkótán

Ọ̀rọ̀ pé jíjí mú omi ilá ní àràárọ̀ kùtùkùtù ń ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ń ṣí ènìyàn lọ́nà, ní bí wọn ò ṣe tíì fi idi rẹ̀ múlẹ̀ pé ilá ní èròjà tó leè ṣe ìwòsàn àìsàn ìtọ̀ ṣúgà. 

Aṣèwádìí yìí pèsè àpilẹ̀kọ afi ìdí òdodo múlẹ̀ yi fún the Dubawa 2021 Kwame KariKari Fellowship pelu Crest FM láti ṣe ìrànwọ́ fún ìfìdí òótọ́ múlẹ̀ nínú iṣẹ́ ìròyìn àti láti mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú síi ní orílẹ̀ èdè yìí.

    PC: Youtube.com5 mins read

News Letter

Subscribe our Email News Letter to get Instant Update at anytime

About Oases News

OASES News is a News Agency with the central idea of diseminating credible, evidence-based, impeccable news and activities without stripping all technicalities involved in news reporting.