Monday, 29 April 2024

Atupa

Atupa (Weird but true!!.) A narration of weird but through stories in Yoruba Language.

Oriki Igbo-Ora (Panegric/Eulogy of Igbo-Ora)

 

Oriki Igbo-Ora (Panegric/Eulogy of Igbo-Ora)
 
Igbo-Ora, a town in Oyo State Nigeria is nicknamed the Twins capital of the world which makes it one of the most extraordinary towns in Africa. The town is a simple town in Oyo state with a simple way of life, made up of mostly farmers and traders. It is considered the Twin capital of the world, and has the stone plinth that boasts of it.
Because more twins are born in Igbo Ora than anywhere else in the world, walking through the town might make you feel like you are seeing double. Almost every house has at least one set of twins.
 
According to Olu (King) Of the town, Oba Jimoh Olajide Titiloye, the town is where there is a large concentration of Twins in the world. He further stated that WHO and other universities have researched the mysterious issue of twin births in Igbo Ora community.
 
The town organizes world twins festival every year. At the elaborate maiden edition in 2018, according to the organisers, about 5,000 twins graced the occasion which was fully supported by the government. In 2019, during the festival, no fewer than 10 women gave birth to twins during the ceremony, the king said.
 
ORIKI IGBO-ORA (PANEGRIC/EULOGY OF IGBO-ORA)
Igbo-ora lasako
Ofokun-bara-diyo
Oroko-roko-magbado -bowale
Ilu taa mo ni igbo-ora titi doni
Tii se ilu alaafin ajagbo
Ode han-un-han-un nise-e-won
Ilu igbo-ora,won wa se bee
Won sope depo
Igbo-ora nibi talejo wo
Tolowo lowo
Nibi ti olori buruku wo to di olorire
Nibi ti won tin se ila orere falejo je
Ilu lajorun ajamu edu
Igbo ora nibi ti lasogba tedo si
Lojo to koko toyo oro de
Okiri-kiri lati reranpa
Atamatase ode ti merin-in so laaye
 
Igbo-ora ilu ogo
Nibi ta won ode nla-nla fi n se ile won
Ogun ibariba to le won de bee
Ilu igbo-ora
Nibi ti ibeji bibi po sini gbogbo agbanla aye
Igbo-ora ni
Omo asogbo dile
Omo asogbe digboro
Omo asakitan doja
Eyin naa leso inu igbe dilu
Ni igbo-ora lasako
Nile BINU OMOTE, olori omo
 
Lasogba Ajadi Aro
Lagaye Ayisa Opo
Lajorun oun Ajade
Ni won jo sode ke sira won
Ooo remo ri
Igbo-ora lo ti de
Igbo ora nile ibarapa
Nibi teranko n gbe fohun bi eniyan
Nile Oyewole Oyerogba Otanbala
Kolorun o de ile fun eniyan re
Nile kabiesi oba to ju oba lo
HRH OBA JIMOH TITILOYE ILUFEMILOYE
Omo asorolu eru bami
Arojo joye
Omo adele teji teji
Omo Opomulero
Maja lekan
Oporoso
Opo gbaja
Baba loni ka rodi laso
Omo bi osi aso
Bi osi ewu
Onirunrun idi laba ma ri
Bi kuru kuru
Bi koko,bi ewo
Eniyan to ba mo iwulo aso
Ko ma fewe owu nudi
Nitori kosohun tin ba oku de boji
Ojo tabaku aso ni ba ni de poro sare
Eni ba fewe owu nudi
Oju aso ni pon oluwa re……
Kabiesi ooooooooooooo
 
Source: My wooden Words 

News Letter

Subscribe our Email News Letter to get Instant Update at anytime

About Oases News

OASES News is a News Agency with the central idea of diseminating credible, evidence-based, impeccable news and activities without stripping all technicalities involved in news reporting.